Ki K’Oju Awon Ipenija Adari L’Agbo Kristeni (2016)

By Rotimi Adedayo
Available Also In English:
The Leadership Challenge: Groanings, Tears And Succour

Ipo adari kii s’oro iru wa ogiri wa; awon ipele amuye wa lati de ki enikeni to de ipo adari. Ninu awon ile-ise nlanla agbaye, awon koko amuye ati titayo la maa nbeere lowo awon to ba fe g’oke. Ninu ise-iranse, Olorun nikan ninu ogbon ailopin re lo maa nyan, ti yoo si fi awon eniyan si ipo adari, eleyi ko si ni nkan se pelu ojo ori, mimo oro iso, iriri tabi bi a ti bi ni.

Sugbon, yiye fun ipo adari kii wa se aabo lowo awon ipenija to pelu ojuse eru wuwo sise adari awon elomiran. Awon ipenija to n k’oju awon adari Kristeni loni ga ti ko se e f’enu so. Kristeni kookan to wa ni ipo adari n k’oju awon ipenija to je wipe o mu ni l’omi, opelope oore-ofe Olorun to wa fun awon adari to ni emi Kristi lati tesiwaju.

Ko si oro sisa fun awon ipenija ti awon to ni eru ise lati dari awon elomiran nk’oju re, boya ninu ise-iranse, oselu tabi l’awon ile-ise nlanla ninu aye. Biba aini awon elomiran pade, l’oju ija-ni-kule ati idite le e mu ni l’omi, sugbon awon ona abayo lati inu iwe mimo ni a se alakale re ninu iwe yi fun awon adari to ni emi Kristi.

Go To:
Main Library Page

Author's Page